Supreme court judgement: Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ PDP fẹ̀hónú hàn nílé ẹjọ́ gíga jùlọ

Gomina Lalong, Gomina Tambuwal, Gomina Ganduje

Oríṣun àwòrán, OTHER

Àkọlé fídíò, Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ PDP fẹ̀hónúhàn nílé ẹjọ́ gíga jùlọ

Lafikun bi ile ẹj to ga julọ lorilẹede Naijiria ṣe dajọ pe Gomina Ganduje ti Kano ati Gomina Tambuwal ti Sokoto lo wọle, ile ẹjọ kan naa ti kede Gomina Simon Lalong gẹgẹ bi ajawe olubori ibo gomina ni ipinlẹ Plateau.

Ọjọ aje ọjọ̀ kẹwaa oṣu kinni ọdun eyi to ṣe gẹlẹ oṣu mẹwaa lẹyin ti ajọ ele5to idibo, INEC da gomina Lalong pada gẹgẹ bi ajawe olubori idibo to waye ninu oṣu kẹta ọdun to kọja.

Jeremiah Useni ti ẹgbẹ oṣelu PDP lo pe ẹjọ naa ni ile ẹjọ giga julọ lati pe ikede ẹgbẹ oṣelu APC nija gẹgẹ bi ẹgbẹ ti ajọ INEC kede.

Ẹwẹ, ile ẹjọ fagi le ipẹjọ rẹ pẹlu ipohun pọ dajọ nile ẹjọ giga julọ labẹ idajọ adajọ Adamu Galinje.

Ile ẹjọ ni olupẹjọ kuna lati fi gbogbo ọna to ni Simon Lalong fi tẹ anfani ati jawe olubori ara rẹ nidi nibi idibo ọjọ kẹsan oṣu kẹta ọdun 2019.

Ọgọọrọ awọn alatilẹyin ẹgbẹ oṣelu PDP lo ṣewọde niluu Abuja lọjọ Aje lẹyin idajọ ileẹjọ giga julọ to f'ountẹ lu Gomina Abdulahi Ganduje gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori nipinlẹ Kano.

Awọn adajọ ẹlẹni meje ti Adajọ agba Naijiria, Muhammed Tanko ṣaaju da ẹjọ ti Abba Yusuf to jẹ oludije lẹgbẹ oṣelu PDP pe lati tako wiwọle Gomina Ganduje ti ẹgbẹ oṣelu APC nu.

Awọn olufẹhonuhan PDP
Awọn olufẹhonuhan PDP

Eyi lo mu kawọn alatilẹyin ẹgbẹ oṣelu PDP bẹrẹ ifẹhonuhan ninu eyi ti wọn ti n sọ pe awọn ko faramọ idajọ ileẹjọ to giga julọ.

Ilé ẹjọ́ gíga jùlọ fi òǹtẹ̀ lu Tambuwal (PDP) gẹ́gẹ́ bíi gómìnà ìpínlẹ̀ Sokoto

Ile ẹjọ to ga julọ ti fi ontẹ lu Aminu Tambuwal gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Sokoto.

Awọn adajọ da ẹjọ oludije fun ipo gomina fẹgbẹ oṣelu APC, Ahmed Aliyu nu lẹyin ti wọn fidi rẹ mulẹ pe Tambuwal lo wọle ibo naa.

Aminu Tambuwal

Oríṣun àwòrán, Facebook/Aminu Tambuwal

Igbẹjọ ti wa ni idaduro bayii lẹyin ti ile ẹjọ ti yanju awuyewuye to jẹyọ ninu ibo gomina ipinlẹ Sokoto ati Kano.

Ẹwẹ, iroyin ti a gbọ ni pe rogbodiyan bẹ silẹ laarin awọn alatilẹyin ẹgbẹ oṣelu PDP ati APC niwaju ileẹjọ to ga gulọ l'Abuja.

kano

Oríṣun àwòrán, @others

Àkọlé àwòrán, Ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria ti fi ountẹ jan Ganduje gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Kano

Ganduje máa bá iṣẹ́ rẹ lọ- ilé ẹjọ́ gíga jùlọ

Awọn adajọ ẹlẹnu meje ti Adajọ agba Naijiria, Muhammed Tanko ṣaaju ti ni ki Gomina Ganduje maa ba iṣẹ rẹ lọ.

Eyi ni idajọ lori ẹjọ ti Abba Yusuf to jẹ oludije lẹgbẹ oṣelu PDP pe tako wiwọle Gomina Ganduje ti ẹgbẹ oṣelu APC ninu eto idibo to kọja.

Ṣaaju ni wọn ti kọkọ gbọ ẹjọ naa nile ẹjọ kotẹmilọrun ni Kano.

Bayii, Adajọ Sylvester Ngwuta sọ pe ko si idi lati tẹsiwaju pẹlu idajọ naa biko ṣe pe ki Gomina maa ba iṣẹ rẹ lọ titi di 2023 gẹgẹ bi gopmina ipinlẹ Kano.

Bala Muhammed, gómìnà ìpínlẹ̀ Bauchi ti dé sílé ẹjọ́ ní Abuja Kano Governorship: Ilé ẹjọ sún ìgbẹ́jọ Ganduje sí ogunjọ oṣù kíní

ile ejo
Àkọlé àwòrán, Fọ́fọ́ ni ilé ẹjọ́ ti kún báyìí látàri ìgbẹ́jọ́ lórí ìdìbò ìpínlẹ̀ Kano, Sokoto àti Bauchi

Bi ẹ ko ba gbagbe lasiko igbẹjọ idibo ipinlẹ Bauchi ti Bala Muhammed n tukọ re lọsẹ to kọja ni wọn ni ara ré ko ya.

Eyi lo si jẹ ki wọn gbe e lo fun itọju nile iwosan nilẹ okeere.

Àkọlé fídíò, Hepatitis: A kò leè kóo nípa dídìmọ́ ara ẹni

Lonii, pẹlu inu fuu, aya fuu lori idajọ ipinlẹ Imo ni awọn ero ṣe pe silẹ ẹjọ, Koda awọn gomina ti ọrọ kan paapaa ti de.

Ọpọlọpọ awọn agbẹjọrọ ni ko ri aaye jọko si ninu ile ẹjọ to ga julọ bayii.

ile ejo
Àkọlé àwòrán, Awon agbejoro ko ri aga joko si nile ejo nitori pe ero ti po ju

Fọ́fọ́ ni ilé ẹjọ́ ti kún báyìí látàri ìgbẹ́jọ́ lórí ìdìbò ìpínlẹ̀ Kano, Sokoto àti Bauchi:

ile ejo
Àkọlé àwòrán, Awon ero lorisirisi ni won ti kun ile ẹjọ giiga lati mọ ibi ti ọrọ maa ja si lonii

Loni ni idajọ ile ẹjọ to ga julọ lori igbẹjọ ẹni ti yoo maa tukọ ipinlẹ Kano, sokoto ati Benue.

Ṣaaju ni oni ọjọ Aje lo yẹ ki ile-ẹjọ to ga ju lọ ni Naijiria dajọ awuyewuye to jẹyọ nibi ibo gomina awọn ipinlẹ naa.

Oludije fun ipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP, Abba Kabir Yusuf lo pe oludije ẹgbẹ oṣelu APC, Abdullahi Umar Ganduje to jawe olubori ninu ibo gomina ipinlẹ Kano lẹjọ.

ile ejo
Àkọlé àwòrán, Ṣaaju, oni ọjọ Aje lo yẹ ki ile-ẹjọ to ga ju lọ ni Naijiria dajọ awuyewuye to jẹyọ nibi ibo gomina awọn ipinlẹ naa.

Ibẹru bojo wa ni ọkan awọn eniyan ipinlẹ naa latari ohun to ṣẹlẹ nile ẹjọ lọṣẹ to kọja lori igbẹjọ ipinlẹ Imo Àsọtẹ́lẹ̀ Fada Mbaka, tó yẹ àga mọ́ gómìnà Imo nídìí rèè

ile ejo
Àkọlé àwòrán, Ohun gbogbo ti wa ni ikale lasti bere igbejo naa

Saaju ni Ile ẹjọ to ga ju lọ lorilẹ-ede Naijiria ti sun igbẹjọ to yẹ ko waye lọsẹ to kọja si oni lori idibo ipinlẹ marun un to ku lẹyin ti wọn dajọ ti ipinlẹ Imo.

Adajọ agba Naijiria, Adajọ Tanko Muhammad lo pa aṣẹ naa lẹyin ti awọn oniṣẹ aabo ko lee kapa aduru ero to wa nibẹ ati ariwo pupọ ninu ile ẹjọ.

Adajọ Muhammad lo dari igbimọ igbẹjọ ẹlẹni meje to jẹ asan adajọ lati gbọ ẹsun awuyewuye to jẹyọ nibi ibo gomina ipinlẹ Bauchi, Kano, Sokoto, Plateau, Benue.

ile ẹjọ
Àkọlé àwòrán, 'Opọlọpọ awọn agbẹjọro lo n forigbari lati fẹnuko lori ọrọ ikẹyin wọn ti yoo gbe are fun onibara wọn
ile ejo
Àkọlé àwòrán, Fọ́fọ́ ni ilé ẹjọ́ ti kún báyìí látàri ìgbẹ́jọ́ lórí ìdìbò ìpínlẹ̀ Kano, Sokoto àti Bauchi
ile ẹjọ.
Àkọlé àwòrán, Awon adajo kookan ti n de sile ejo to ga julọ nilu Abuja

Gbogbo ni awọn agbofinro kun ile ẹjọ f